Genesis 24:47 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà náà ni mo bi í ọmọ ẹni tí í ṣe. Ó dá mi lóhùn pé, Betueli ọmọ Nahori, tí Milika bí fún un ni baba òun. Nígbà tí mo gbọ́ bẹ́ẹ̀, mo fi òrùka sí imú rẹ̀, mo sì fi ẹ̀gbà ọwọ́ bọ̀ ọ́ lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi si bi i, mo si wipe, Ọmọbinrin tani iwọ iṣe? o si wipe, Ọmọbinrin Betueli, ọmọ Nahori, ti Milka bí fun u: emi si fi oruka si i ni imu, ati jufù si ọwọ́ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, ‘ọmọ ta ní ìwọ í ṣe?’ “Ó sì wí fún mi pé, ‘ọmọbìnrin Bétúélì tí í ṣe ọmọ Náhórì ni òun, Mílíkà sì ni ìyá òun.’ “Nígbà náà ni mo fi òrùka náà bọ imú rẹ̀, mo sì fi ẹ̀gbà-ọwọ́ náà si ní ọwọ́.