Genesis 24:54 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà náà ni òun ati àwọn tí wọ́n bá a wá tó jẹ, tí wọ́n sì mu, wọ́n sùn níbẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà. Bí wọ́n ti jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, iranṣẹ Abrahamu wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n lọ jíṣẹ́ fún oluwa mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si jẹ, nwọn si mu, on ati awọn ọkunrin ti o wà pẹlu rẹ̀, nwọn si wọ̀ nibẹ̀ li oru ijọ́ na; nwọn si dide li owurọ̀, o si wipe, Ẹ rán mi lọ si ọdọ oluwa mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn náà ni òun àti àwọn ọkùnrin tí ó bá a wá tó jẹ, tí wọ́n sì mu, tí wọn sì sùn níbẹ̀ ní òru ọjọ́ náà. Bí wọ́n ti dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó wí pé, “Ẹ rán mi padà lọ sí ọ̀dọ̀ olúwa mi.”