Genesis 24:60 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n súre fún Rebeka, wọ́n wí pé, “Arabinrin wa, o óo bírún, o óo bígba. Àwọn ọmọ rẹ yóo máa borí àwọn ọ̀tá wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si súre fun Rebeka, nwọn si wi fun u pe, Iwọ li arabinrin wa, ki iwọ, ki o si ṣe iya ẹgbẹgbẹrun lọnà ẹgbãrun, ki irú-ọmọ rẹ ki o si ni ẹnubode awọn ti o korira wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì súré fún Rèbékà, wọn sì wí fun un pé, “Arábìnrin wa, ìwọ yóò di ìyá ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún. Ǹjẹ́ kí àwọn irú-ọmọ rẹ kí ó gba ibodè ọ̀ta a wọn.”