Genesis 24:63 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, ó lọ ṣe àṣàrò ninu pápá, ojú tí ó gbé sókè, ó rí i tí àwọn ràkúnmí ń bọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Isaaki si jade lọ ṣe àṣaro li oko li aṣalẹ: o si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri i, si kiyesi i, awọn ibakasiẹ mbọ̀wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ísáákì sáà jáde lọ sí oko ni ìrọ̀lẹ́ láti ṣe àsàrò, bí ó sì ti gbé ojú sókè, ó rí àwọn ràkunmí tí ń bọ̀ wá.