Genesis 24:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun ọ̀run, tí ó mú mi jáde láti ilé baba mi, ati ilẹ̀ tí wọ́n bí mi sí, tí ó bá mi sọ̀rọ̀, tí ó sì búra fún mi pé, àwọn ọmọ mi ni òun yóo fi ilẹ̀ yìí fún, yóo rán angẹli rẹ̀ ṣáájú rẹ, o óo sì fẹ́ aya wá fún ọmọ mi láti ibẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA Ọlọrun ọrun, ti o mu mi lati ile baba mi wá, ati lati ilẹ ti a bi mi, ẹniti o sọ fun mi, ti o si bura fun mi, wipe, Irú-ọmọ rẹ li emi o fi ilẹ yi fun; on ni yio rán angeli rẹ̀ ṣaju rẹ, iwọ o si fẹ́ aya lati ibẹ̀ fun ọmọ mi wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“OLÚWA, Ọlọ́run ọ̀run tí ó mú mi jáde láti ilẹ̀ baba mi àti ní ilẹ̀ tí a bí mi, tí ó bá mi sọ̀rọ̀ tí ó sì búra fún mi pé, ‘Irú ọmọ rẹ ni n ó fi ilẹ̀ yìí fún’, yóò rán ańgẹ́lì rẹ̀ ṣáájú rẹ, kí ìwọ kí ó lè rí aya fẹ́ wá fún ọmọ mi láti ibẹ̀.