Genesis 25:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ ń ti ara wọn síhìn-ín sọ́hùn-ún ninu rẹ̀, ó sì wí pé, “Bí ó bá jẹ́ pé báyìí ni yóo máa rí, kí ni mo kúkú wà láàyè fún?” Ó bá lọ wádìí ọ̀rọ̀ náà wò lọ́dọ̀ OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ si njàgudu ninu rẹ̀: o si wipe, bi o ba ṣe pe bẹ̃ni yio ri, ẽṣe ti mo fi ri bayi? O si lọ bère lọdọ OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ náà ń gbún ara wọn nínú rẹ̀, ó sì wí pé, “Èéṣe tí èyí ń ṣẹlẹ̀ sí mi,” ó sì lọ béèrè lọ́dọ̀ OLÚWA.