Genesis 25:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA wí fún un pé, “Orílẹ̀-èdè meji ni ó wà ninu rẹ, a óo sì pín àwọn oríṣìí eniyan meji tí o óo bí níyà, ọ̀kan yóo lágbára ju ekeji lọ, èyí ẹ̀gbọ́n ni yóo sì máa sin àbúrò.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si wi fun u pe, orilẹ-ède meji ni mbẹ ninu rẹ, irú enia meji ni yio yà lati inu rẹ: awọn enia kan yio le jù ekeji lọ; ẹgbọ́n ni yio si ma sìn aburo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì wí fún un pé, “Orílẹ̀ èdè méjì ni ń bẹ nínú rẹ, àwọn méjì tí ó jáde láti inú rẹ yóò sì pínyà, àwọn ènìyàn kan yóò jẹ́ alágbára ju èkejì lọ, ẹ̀gbọ́n yóò sì máa sin àbúrò.”