Genesis 25:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Esau sọ fún Jakọbu pé, “Jọ̀wọ́ fún mi jẹ ninu ẹ̀bẹ tí ó pupa yìí nítorí pé ebi ń pa mí kú lọ.” (Nítorí ọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n ṣe ń pè é ní Edomu.)
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Esau si wi fun Jakobu pe, Emi bẹ̀ ọ, fi ìpẹtẹ rẹ pupa nì bọ́ mi; nitori ti o rẹ̀ mi: nitori na li a ṣe npè orukọ rẹ̀ ni Edomu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó wí fún Jákọ́bù pé, “Ṣe kánkán, fún mi jẹ lára àsáró rẹ pupa yìí, nítorí ebi ń pa mi gidigidi.” (Ìdí èyí ni wọn fi ń pe Éṣáù ni Édómù).