Genesis 26:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà Abimeleki kìlọ̀ fún gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan ọkunrin yìí tabi aya rẹ̀, pípa ni wọn yóo pa á.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Abimeleki si kìlọ fun gbogbo awọn enia rẹ̀ wipe, Ẹnikẹni ti o ba tọ́ ọkunrin yi tabi aya rẹ̀, kikú ni yio kú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Ábímélékì pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ọkùnrin yìí tàbí aya rẹ̀ yóò jẹ̀bi ikú”