Genesis 26:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó kúrò níbẹ̀, ó lọ gbẹ́ kànga mìíràn, ẹnikẹ́ni kò sì bá a jà sí i, ó bá sọ ọ́ ní Rehoboti, ó wí pé, “Nisinsinyii Ọlọrun ti pèsè ààyè fún wa, a óo sì pọ̀ sí i ní ilẹ̀ yìí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣí kuro nibẹ̀, o si wà kanga miran: nwọn kò si jà nitori rẹ̀: o si pè orukọ rẹ̀ ni Rehoboti; o si wipe, Njẹ nigbayi li OLUWA tó fi àye fun wa, awa o si ma bisi i ni ilẹ yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì tún kúrò níbẹ̀, ó sì gbẹ́ kànga mìíràn, wọn kò sì já sí èyí rárá, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Réhóbótì, ó wí pé, “Nísinsìnyìí, OLÚWA ti fi àyè gbà wá, a ó sí i gbilẹ̀ sì ni ilẹ̀ náà.”