Genesis 26:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA sì fara hàn án ní òru ọjọ́ tí ó rin ìrìn àjò náà, ó ní, “Èmi ni Ọlọrun Abrahamu, baba rẹ, má bẹ̀rù, nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo bukun ọ, n óo sì sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ nítorí ti Abrahamu iranṣẹ mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si farahàn a li oru ọjọ́ na, o si wipe, Emi li Ọlọrun Abrahamu, baba rẹ: máṣe bẹ̀ru, nitori ti emi wà pẹlu rẹ, emi o si busi i fun ọ, emi o si mu irú-ọmọ rẹ rẹ̀, nitori Abrahamu ọmọ-ọdọ mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní òru ọjọ́ tí ó dé ibẹ̀, OLÚWA sì fara hàn-án, ó sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù baba rẹ: Má ṣe bẹ̀rù nítorí èmi wà fún ọ, èmi yóò sì sọ iye ìran rẹ di púpọ̀, nítorí Ábúráhámù ìránṣẹ́ mi.”