Genesis 26:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn ará ìlú náà bèèrè bí Rebeka ti jẹ́ sí i, ó sọ fún wọn pé arabinrin òun ni. Ẹ̀rù bà á láti jẹ́wọ́ fún wọn pé iyawo òun ni, nítorí ó rò pé àwọn ará ìlú náà lè pa òun nítorí pe Rebeka jẹ́ arẹwà obinrin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọkunrin ibẹ̀ na bi i lẽre niti aya rẹ̀: o si wipe, Arabinrin mi ni: nitoriti o bẹ̀ru ati wipe, Aya mi ni; o ni, ki awọn ọkunrin ibẹ̀ na ki o má ba pa mi nitori Rebeka; nitoriti on li ẹwà lati wò.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ọkùnrin ìlú náà béèrè bí t'òun àti ti Rèbékà ti jẹ́, ó dáhùn pé, arábìnrin òun ní í ṣe nítorí pé ẹ̀rù bà á láti jẹ́wọ́ wí pé aya òun ni; ó ń rò ó wí pé wọ́n le pa òun nítorí Rèbékà, nítorí ti Rèbékà lẹ́wà púpọ̀.