Genesis 27:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà náà ni ó wí pé, “Gbé oúnjẹ náà súnmọ́ mi, kí n jẹ ninu ẹran tí ọmọ mi pa, kí n sì súre fún ọ.” Jakọbu bá gbé oúnjẹ náà súnmọ́ ọn, ó jẹ ẹ́, ó bu ọtí waini fún un, ó sì mu ún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Gbé e sunmọ ọdọ mi, emi o si jẹ ninu ẹran-igbẹ́ ọmọ mi, ki ọkàn mi ki o le sure fun ọ. O si gbé e sunmọ ọdọ rẹ̀, o si jẹ: o si gbé ọti-waini fun u, on si mu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Ísáákì wí pé “Gbé ẹran igbó náà súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi, kí èmi kí ó jẹ ẹ́, kí èmi sì súre fún ọ láti inú ọkàn mi wá.” Jákọ́bù sì gbé e wá ó sì jẹ ẹ́, ó sì tún fún-un ní wáìnì, ó sì mú un pẹ̀lú.