Genesis 27:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí àwọn eniyan máa sìn ọ́, kí àwọn orílẹ̀-èdè sì máa tẹríba fún ọ. Ìwọ ni o óo máa ṣe olórí àwọn arakunrin rẹ, àwọn ọmọ ìyá rẹ yóo sì máa tẹríba fún ọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé ọ, òun ni èpè yóo mọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì súre fún ọ, ìre yóo mọ́ ọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki enia ki o mã sìn ọ, ki orilẹ-ède ki o mã tẹriba fun ọ: mã ṣe oluwa awọn arakunrin rẹ, ki awọn ọmọ iya rẹ ki o tẹriba fun ọ: ifibú li awọn ẹniti o fi ọ bú, ibukún si ni fun awọn ẹniti o sure fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó máa sìn ọ́, kí àwọn ènìyàn sì máa tẹríba fún ọ, máa ṣe olórí àwọn arákùnrin rẹ, kí àwọn ìyekan rẹ sì máa wólẹ̀ fún ọ Ègún ni fún gbogbo ẹni tí ń fi ọ́ ré, Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó súre fún ọ.”