Genesis 27:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Òun náà se oúnjẹ aládùn, ó gbé e tọ baba rẹ̀ wá, ó wí fún un pé, “Baba mi, dìde, kí o jẹ ninu ẹran tí èmi ọmọ rẹ pa, kí o lè súre fún mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On pẹlu si ti sè ẹran adidùn, o si mu u tọ̀ baba rẹ̀ wá, o si wi fun baba rẹ̀ pe, Ki baba mi ki o dide ki o si jẹ ninu ẹran-igbẹ́ ọmọ rẹ̀, ki ọkàn rẹ le sure fun mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun pẹ̀lú ṣe ẹran dídùn, ó sì gbé e tọ baba rẹ̀ wá, ó sì wí fún un pé, “Baba mi, dìde jókòó, kí o sì jẹ nínú ẹran igbó tí mo ti ṣè, kí o sì súre fún mi.”