Genesis 27:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ara Isaaki bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n gidigidi, ó wí pé, “Ta ló ti kọ́ pa ẹran tí ó gbé e tọ̀ mí wá, tí mo jẹ gbogbo rẹ̀ tán kí o tó dé? Mo sì ti súre fún un. Láìsí àní àní, ìre náà yóo mọ́ ọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Isaaki si warìri gidigidi rekọja, o si wipe, Tani nla? tali ẹniti o ti pa ẹran-igbẹ́, ti o si gbé e tọ̀ mi wá, emi si ti jẹ ninu gbogbo rẹ̀, ki iwọ ki o to de, emi si ti sure fun u? nitõtọ a o si bukún fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Ísáákì wárìrì gidigidi, ó sì wí pé, “Ta ni ẹni náà, tí ó ti pa ẹran igbó tí ó sì ti gbe wá fún mi, tí mo sì ti jẹ ẹ́ kí ó tó dé? Mo sì ti súre fún un sì wò ó dájúdájú a ó sì bùkún un”