Genesis 27:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Esau gbọ́ ohun tí baba rẹ̀ sọ, ó fi igbe ta, ó sọkún kíkorò, ó wí pé, “Baba mi, súre fún èmi náà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Esau gbọ́ ọ̀rọ baba rẹ̀, o fi igbe nlanla ta, o si sun ẹkun kikorò gidigidi, o si wi fun baba rẹ̀ pe, Sure fun mi, ani fun emi pẹlu, baba mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Ísọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ baba rẹ̀, ó ké, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sunkún kíkorò, ó sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Baba mi súre fún èmi náà, àní fún èmi náà pẹ̀lú.”