Genesis 27:37 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Isaaki dá a lóhùn, ó ní, “Mo ti fi ṣe olórí rẹ, gbogbo àwọn arakunrin rẹ̀ ni mo sì ti fún un láti fi ṣe iranṣẹ, mo ti fún un ní ọ̀pọ̀ ọkà ati ọtí waini. Kí ló tún wá kù tí mo lè ṣe fún ọ, ọmọ mi?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Isaaki si dahùn o si wi fun Esau pe, Wõ, emi ti fi on ṣe oluwa rẹ, ati gbogbo awọn arakunrin rẹ̀ li emi ti fi ṣe iranṣẹ rẹ̀; ati ọkà ati ọti-waini ni mo fi gbè e: ewo li emi o ha ṣe fun ọ nisisiyi, ọmọ mi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ísáákì sì dá Ísọ̀ lóhùn pé, “Mo ti fi ṣe olórí rẹ àti àwọn ìbátan rẹ ni mo fi ṣe ìránṣẹ́ fún-un, àti oúnjẹ àti wáìnì ni mo ti fi lé e lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀, kí ni ó tún kù tí ǹ bá tún fún ọ báyìí ọmọ mi?”