Genesis 27:40 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Pẹlu idà rẹ ni o óo fi wà láàyè, arakunrin rẹ ni o óo sì máa sìn, ṣugbọn nígbà tí ó bá yá, o óo já ara rẹ gbà, o óo sì bọ́ àjàgà rẹ̀ kúrò lọ́rùn rẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nipa idà rẹ ni iwọ o ma gbé, iwọ o si ma sìn arakunrin rẹ; yio si ṣe nigbati iwọ ba di alagbara tan, iwọ o já àjaga rẹ̀ kuro li ọrùn rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nípa idà ni ìwọ yóò máa gbé, ìwọ yóò sì máa sin àbúrò rẹ, ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, nígbà tí ìwọ bá di alágbára ìwọ yóò já àjàgà rẹ̀-kúrò lọ́rùn rẹ ìwọ yóò sì di òmìnira.”