Genesis 27:42 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn wọ́n sọ ohun tí Esau, àkọ́bí Rebeka ń wí fún Rebeka ìyá rẹ̀. Rebeka bá ranṣẹ pe Jakọbu, ó wí fún un pé, “O jẹ́ mọ̀, Esau ẹ̀gbọ́n rẹ ń dá ara rẹ̀ lọ́kàn le pẹlu ìpinnu láti pa ọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A si sọ ọ̀rọ Esau akọ́bi rẹ̀ wọnyi fun Rebeka: on si ranṣẹ o si pè Jakobu, ọmọ rẹ̀ aburo, o si wi fun u pe, Kiyesi i, Esau, arakunrin rẹ, ntù ara rẹ ninu niti rẹ lati pa ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Rèbékà sì gbọ́ ohun tí Ísọ̀ àkọ́bí rẹ̀ wí, ó sì ránṣẹ́ sí Jákọ́bù, ó sì wí fun un pé, “Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ ń tu ara rẹ̀ nínú pẹ̀lú èrò àti pa ọ́.