Genesis 27:45 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
tí inú rẹ̀ yóo yọ́, tí yóo sì gbàgbé ohun tí o ti ṣe sí i, n óo wá ranṣẹ pè ọ́ pada nígbà náà. Mo ha gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀ ẹ̀yin mejeeji lọ́jọ́ kan náà bí?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Titi inu arakunrin rẹ yio fi tutu si ọ, ti yio si fi gbagbe ohun ti o fi ṣe e: nigbana li emi o ranṣẹ mu ọ lati ibẹ̀ wá: ẽṣe ti emi o fi fẹ́ ẹnyin mejeji kù ni ijọ́ kanṣoṣo?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ẹ̀gbọ́n rẹ kò bá bínú sí ọ mọ́, tí ó sì ti gbàgbé ohun tí ìwọ ṣe sí i, èmí ó ránṣẹ́ sí ọ láti padà wá, Èéṣe tí èmi ó fi pàdánù ẹ̀yin méjèèjì ní ọjọ́ kan náà?”