Genesis 27:46 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Rebeka sọ fún Isaaki, ó ní, “Ọ̀rọ̀ àwọn obinrin Hiti wọnyi mú kí ayé sú mi. Bí Jakọbu bá lọ fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn obinrin ará Hiti, irú àwọn obinrin ilẹ̀ yìí, irú ire wo ni ó tún kù fún mi láyé mọ́?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Rebeka si wi fun Isaaki pe, Agara aiye mi ma dá mi nitori awọn ọmọbinrin Heti, bi Jakobu ba fẹ́ aya ninu awọn ọmọbinrin Heti, bi irú awọn wọnyi yi iṣe ninu awọn ọmọbinrin ilẹ yi, aiye mi o ha ti ri?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Rèbékà wí fún Isaaki pé, “Ayé sì sú mi nítorí àwọn ọmọbìnrin Hétì wọ̀nyí. Bí Jákọ́bù bá fẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Hétì wọ̀nyí, ó kúkú sàn kí n má wà láàyè.”