Genesis 28:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó sùn, ó lá àlá kan, ó rí àkàsọ̀ kan lójú àlá, wọ́n gbé e kalẹ̀, orí rẹ̀ kan ojú ọ̀run. Ó wá rí i tí àwọn angẹli Ọlọrun ń gùn ún lọ sókè sódò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si lá alá, si kiyesi i, a gbé àkasọ kan duro lori ilẹ, ori rẹ̀ si de oke ọrun: si kiyesi i, awọn angeli Ọlọrun ngoke, nwọn si nsọkalẹ lori rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì lá àlá pé, a gbé àkàsọ̀ kan dúró ti ó fi ìdí lélẹ̀, orí rẹ̀ sì kan ọ̀run, àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run sì ń gòkè, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀.