Genesis 28:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ rẹ yóo pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, o óo sì gbilẹ̀ káàkiri sí ìhà ìwọ̀ oòrùn ati sí ìhà ìlà oòrùn, sí ìhà àríwá ati sí ìhà gúsù nípasẹ̀ rẹ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo bukun aráyé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Irú-ọmọ rẹ yio si ri bi erupẹ̀ ilẹ, iwọ o si tàn kalẹ si ìha ìwọ-õrùn, ati si ìha ìla-õrùn, ati si ìha ariwa, ati si ìha gusù: ninu rẹ, ati ninu irú-ọmọ rẹ li a o bukún fun gbogbo ibatan aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìran rẹ yóò pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, ìwọ yóò sì tànkálẹ̀ dé ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn, àti dé gúsù àti àríwá. A ó sì bùkún gbogbo orílẹ̀ èdè ayé nípaṣẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ.