Genesis 28:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Esau rí i pé Isaaki ti súre fún Jakọbu, ó sì ti rán an lọ sí Padani-aramu kí ó lọ fẹ́ iyawo, ati pé nígbà tí ó ń súre fún un, ó pàṣẹ fún un pé kò gbọdọ̀ fẹ́ ninu àwọn ọmọbinrin ará Kenaani.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Esau ri pe Isaaki sure fun Jakobu ti o si rán a lọ si Padan-aramu, lati fẹ́ aya lati ibẹ̀; ati pe bi o ti sure fun u, o si kìlọ fun u wipe, iwọ kò gbọdọ fẹ́ aya ninu awọn ọmọbinrin Kenaani;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Ísọ̀ gbọ pé, Ísáákì ti ṣúre fún Jákọ́bù, ó sì ti ran Jákọ́bù lọ sí Padani-Árámù láti fẹ́ aya níbẹ̀ àti pé nígbà tí ó ṣúre fún un, ó kìlọ̀ fun un pé, kò gbọdọ̀ fẹ́ nínú àwọn ọmọbìnrin Kénánì