Genesis 29:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Labani gbọ́ ìròyìn ayọ̀ náà pé, Jakọbu ọmọ arabinrin òun dé, ó sáré lọ pàdé rẹ̀, ó dì mọ́ ọn, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, ó sì mú un wá sí ilé. Jakọbu ròyìn ohun gbogbo tí ó ti ṣẹlẹ̀ fún Labani.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe ti Labani gburó Jakobu, ọmọ arabinrin rẹ̀, o sure lọ ipade rẹ̀, o si gbá a mú, o si fi ẹnu kò o li ẹnu, o si mu u wá si ile rẹ̀. On si ròhin gbogbo nkan wọnni fun Labani.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní keté tí Lábánì gbúròó Jákọ́bù ọmọ arábìnrin rẹ̀, ó jáde lọ pàdé Jákọ́bù, ó dì mọ́ ọn, ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu, ó sì mú un lọ sí ilé. Nigbà náà ni Jákọ́bù ròyìn ohun gbogbo fún un.