Genesis 29:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jakọbu bá sin Labani fún ọdún meje nítorí Rakẹli, ó sì dàbí ọjọ́ mélòó kan lójú rẹ̀ nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí Rakẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jakobu si sìn i li ọdún meje fun Rakeli; nwọn sì dabi ijọ́ melokan li oju rẹ̀ nitori ifẹ́ ti o fẹ́ ẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jákọ́bù sì ṣiṣẹ́ sin Lábánì fún ọdun méje láti fẹ́ Rákélì. Àwọn ọdún wọ̀nyí sì dà bí ọjọ́ díẹ̀ lára rẹ̀, nítorí ó fẹ́ràn rẹ̀.