Genesis 29:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí gbogbo àwọn olùṣọ́-aguntan bá da aguntan wọn dé ìdí kànga yìí ni wọ́n tó ń yí òkúta náà kúrò lẹ́nu kànga. Lẹ́yìn náà, wọn á fún àwọn aguntan wọ́n lómi mu, wọ́n á sì yí òkúta náà pada sẹ́nu kànga.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nibẹ̀ ni gbogbo awọn agbo-ẹran kojọ pọ̀ si: nwọn si fun awọn agutan li omi, nwọn si tun yí okuta dí ẹnu kanga si ipò rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí gbogbo agbo ẹran bá péjọ pọ̀ sí ibẹ̀ tán ni àwọn darandaran yóò tó yí òkúta náà kúrò, tí wọn yóò sì fún àwọn ẹran náà ní omi, tí wọ́n bá sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ tán, wọn yóò tún yí òkúta náà padà sí ẹnu kànga náà.