Genesis 29:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó tún bi wọ́n pé, “Ṣé alaafia ni ó wà?” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Alaafia ni, wò ó, Rakẹli, ọmọbinrin rẹ̀, ni ó ń da aguntan bọ̀ ní ọ̀kánkán yìí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si bi wọn pe, Alafia ki o wà bi? nwọn si wipe Alafia ni; si kiyesi i, Rakeli, ọmọbinrin rẹ̀ mbọ̀wá pẹlu ọwọ́-ẹran.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jákọ́bù béèrè pé, “Ṣe àlàáfíà ni ó wà?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni. Wò ó, Rákélì ọmọ rẹ̀ ni ó ń bọ̀ yìí pẹ̀lú agbo àgùntàn.”