Genesis 29:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jakọbu sọ pé, “Oòrùn ṣì wà lókè, kò tíì tó àkókò láti kó àwọn ẹran jọ sójú kan, ẹ tètè fún àwọn aguntan ní omi mu, kí ẹ sì dà wọ́n pada lọ jẹ koríko sí i.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Kiyesi i, ọjọ́ mbẹ sibẹ̀, bẹ̃ni kò tó akokò ti awọn ẹran yio wọjọ pọ̀: ẹ fun awọn agutan li omi, ki ẹ si lọ ibọ́ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí pé, “Kíyèsi, ilẹ̀ ò tí ì sú, kò tì í tó àkókò fún àwọn ohun ọ̀sìn láti wọ̀. Ẹ fún àwọn ẹran wọ̀nyí ní omi, kí ẹ ba à le tètè dà wọ́n padà láti jẹun.”