Genesis 3:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun bá sọ fún ejò náà pé, “Nítorí ohun tí o ṣe yìí, o di ẹni ìfibú jùlọ láàrin gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn ati àwọn ẹranko. Àyà rẹ ni o óo máa fi wọ́ káàkiri, erùpẹ̀ ni o óo sì máa jẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA Ọlọrun si wi fun ejò na pe, nitori ti iwọ ti ṣe eyi, a fi iwọ bú ninu gbogbo ẹran ati ninu gbogbo ẹranko igbẹ; inu rẹ ni iwọ o ma fi wọ́, erupẹ ilẹ ni iwọ o ma jẹ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni OLÚWA Ọlọ́run wí fún ejò náà pé, “Nítorí tí ìwọ ti ṣe èyí, “Ègún ni fún ọ ju gbogbo ohun ọ̀sìn àti gbogbo ẹran igbó tó kù lọ! Àyà rẹ ni ìwọ yóò fi máa wọ́, ìwọ yóò sì máa jẹ erùpẹ̀ ilẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

Recommended Reading