Genesis 3:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo dá ọ̀tá sí ààrin ìwọ ati obinrin náà, ati sí ààrin atọmọdọmọ rẹ ati atọmọdọmọ rẹ̀. Wọn óo máa fọ́ ọ lórí, ìwọ náà óo sì máa bù wọ́n ní gìgísẹ̀ jẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si fi ọta sãrin iwọ ati obinrin na, ati sãrin irú-ọmọ rẹ ati irú-ọmọ rẹ̀: on o fọ́ ọ li ori, iwọ o si pa a ni gigĩsẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò sì fi ọ̀tá sí àárin ìwọ àti obìnrin náà, àti sí àárín irú ọmọ rẹ àti irú ọmọ obìnrin náà; òun yóò fọ́ orí rẹ ìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀.”