Genesis 3:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, OLUWA Ọlọrun wí pé, “Nisinsinyii tí ọkunrin náà ti dàbí wa, tí ó sì ti mọ ire yàtọ̀ sí ibi, kí ó má lọ mú ninu èso igi ìyè, kí ó jẹ ẹ́, kí ó sì wà láàyè títí lae.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA Ọlọrun si wipe, Wò o, ọkunrin na dabi ọkan ninu wa lati mọ̀ rere ati bururu: njẹ nisisiyi ki o má ba nà ọwọ́ rẹ̀ ki o si mu ninu eso igi ìye pẹlu, ki o si jẹ, ki o si yè titi lai;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA Ọlọ́run sì wí pé, “Ọkùnrin náà ti dàbí ọ̀kan lára wa, ó mọ rere àti búburú. A kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó na ọwọ́ rẹ̀ kí ó mú lára èṣo igi ìyè kí ó sì jẹ, kí ó sì wà láàyè títí láéláé.”