Genesis 30:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní àkókò ìkórè ọkà alikama, Reubẹni bá wọn lọ sí oko, ó sì já èso mandiraki bọ̀ fún Lea ìyá rẹ̀. Nígbà tí Rakẹli rí i, ó bẹ Lea pé kí ó fún òun ninu èso mandiraki ọmọ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li akokò ìgba ikore alikama, Reubeni si lọ, o si ri eso mandraki ni igbẹ́, o si mú wọn fun Lea iya rẹ̀ wá ile. Nigbana ni Rakeli wi fun Lea pe, Emi bẹ̀ ọ, bùn mi ninu mandraki ọmọ rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kan, ní àkókò ìkórè ọkà jéró, Rúbẹ́nì jáde lọ sí oko, ó sì rí ọ̀gbòn mádírákì, ó sì mu un tọ Líà ìyá rẹ̀ wá. Rákélì sì wí fún Líà pé, “Jọ̀wọ́ fún mi ní ara mádírákì tí ọmọ rẹ mú wá.”