Genesis 30:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Lea dá a lóhùn pé, “O gba ọkọ mọ́ mi lọ́wọ́, kò tó ọ, o tún fẹ́ gba èso mandiraki ọmọ mi lọ́wọ́ mi?” Rakẹli bá dá a lóhùn, ó ní: “Bí o bá fún mi ninu èso mandiraki ọmọ rẹ, ọ̀dọ̀ rẹ ni Jakọbu yóo sùn lálẹ́ òní.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun u pe, Iṣe nkan kekere ti iwọ gbà ọkọ lọwọ mi? iwọ si nfẹ́ gbà mandraki ọmọ mi pẹlu? Rakeli si wipe, Nitori na ni yio ṣe sùn tì ọ li alẹ yi nitori mandraki ọmọ rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Líà da lóhùn pé, “Ọkọ mi tí o gbà kò tó kọ́? Ṣe ìwọ yóò tún gba mádírákì ọmọ mi pẹ̀lú?” Rákélì sì dáhùn pé, “Ó dára, yóò sùn tì ọ́ lálẹ́ yìí nítorí mádírákì ọmọ rẹ.”
Recommended Reading