Genesis 30:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ìrọ̀lẹ́, nígbà tí Jakọbu ti oko dé, Lea jáde lọ pàdé rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Ọ̀dọ̀ mi ni o gbọdọ̀ sùn ní alẹ́ òní, èso mandiraki ọmọ mi ni mo fi san owó ọ̀yà rẹ. Jakọbu bá sùn lọ́dọ̀ rẹ̀ di ọjọ́ keji.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jakobu si ti inu oko dé li aṣalẹ, Lea si jade lọ ipade rẹ̀, o si wipe, Iwọ kò le ṣe aima wọle tọ̀ mi wá, nitori ti emi ti fi mandraki ọmọ mi bẹ̀ ọ li ọ̀wẹ. On si sùn tì i li oru na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, nígbà tí Jákọ́bù ti oko dé ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, Líà jáde lọ pàde rẹ̀, ó sì wí pé, “O ní láti sun ọ̀dọ̀ mi ní alẹ́ yìí nítorí mo ti fi mánídárákì tí ọmọ mi wá bẹ̀ ọ́ lọ́wẹ̀.” Nítorí náà ni Jákọ́bù sùn tì í ní alẹ́ ọjọ́ náà.