Genesis 30:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ní, “Ọlọrun ti fi ẹ̀bùn rere fún mi, nígbà yìí ni ọkọ mi yóo tó bu ọlá fún mi, nítorí pé mo bí ọkunrin mẹfa fún un,” nítorí náà ó sọ ọmọ náà ní Sebuluni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lea si wipe, Ọlọrun ti fun mi li ẹ̀bun rere; nigbayi li ọkọ mi yio tó ma bá mi gbé, nitori ti mo bí ọmọkunrin mẹfa fun u: o si pè orukọ rẹ̀ ni Sebuluni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Líà tún wí pé “Ọlọ́run ti fún mi ní ẹ̀bùn iyebíye, nígbà yìí ni ọkọ mi yóò máa bu ọlá fún mi.” Nítorí náà ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ni Ṣébúlúnì.