Genesis 30:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Labani bá bi í léèrè pé, “Kí ni kí n máa fún ọ?” Jakọbu dáhùn pé, “Má fún mi ní ohunkohun, bí o bá gbà láti ṣe ohun kan fún mi, n óo tún máa bá ọ tọ́jú àwọn agbo ẹran rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si bi i pe, Kili emi o fi fun ọ? Jakobu si wi pe, Iwọ máṣe fun mi li ohun kan: bi iwọ o ba le ṣe eyi fun mi, emi o ma bọ́, emi o si ma ṣọ́ agbo-ẹran rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì tún béèrè wí pé, “Kín ni kí èmi ó fi fún ọ?” Jákọ́bù dáhùn pé, “Má fun mi ni ohunkóhun, ṣùgbọ́n bí ìwọ yóò bá ṣe ohun tí mo fẹ́ sọ yìí, èmi yóò sì máa bá ọ tọ́jú àwọn agbo ẹran rẹ, èmi yóò sì máa bọ́ wọn.