Genesis 30:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jẹ́ kí n bọ́ sí ààrin àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ lónìí, kí n sì ṣa gbogbo ọmọ aguntan dúdú, ati gbogbo ọmọ ewúrẹ́ ati aguntan tí ó ní dúdú tóótòòtóó lára, tí ó dàbí adíkálà, irú àwọn ẹran wọnyi ni n óo máa gbà fún iṣẹ́ tí mò ń ṣe fún ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o là gbogbo agbo-ẹran rẹ já loni, emi o mú gbogbo ẹran abilà ati alamì kuro nibẹ̀, ati gbogbo ẹran pupa rúsurusu kuro ninu awọn agutan, ati gbogbo ẹran alamì ati abilà ninu awọn ewurẹ: eyi ni yio si ma ṣe ọ̀ya mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jẹ́ kí èmi kí ó la agbo ẹran kọjá ní òní, èmi yóò sì mú gbogbo àgùntàn onílà àti èyí tí ó ní àmì, àti gbogbo àgbò dúdú pẹ̀lú ewúrẹ́ onílà tàbí tí ó ní àmì. Àwọn wọ̀nyí ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ mi.