Genesis 30:33 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ ni òdodo mi yóo jẹ́rìí gbè mí ní ọjọ́ iwájú, nígbà tí o bá wá wo ọ̀yà mi. Èyíkéyìí tí kò bá jẹ́ dúdú ninu àwọn aguntan, tabi ewúrẹ́ tí àwọ̀ rẹ̀ kò bá ní dúdú tóótòòtóó tí o bá rí láàrin àwọn ẹran mi, a jẹ́ pé mo jí i gbé ni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ododo mi yio si jẹ mi li ẹrí li ẹhin-ọla nigbati iwọ o wá wò ọ̀ya mi: gbogbo eyiti kò ba ṣe abilà ati alami ninu awọn ewurẹ, ti kò si ṣe pupa rúsurusu ninu awọn agutan, on na ni ki a kà si mi li ọrùn bi olè.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òtítọ́ inú mi yóò sì jẹ́rìí fún mi ní ọjọ́ iwájú nígbà tí ìwọ bá wo owó-iṣẹ́ mi tí ìwọ san fún mi, yóò sì ṣe pé gbogbo èyí tí kì í bá ṣe onílà tàbí alámì nínú ewúrẹ́ tàbí tí kì í ṣe dúdú nínú àgùntàn, tí o bá rí ni ọ̀dọ̀ mi ni kí o kà sí mi lọ́rùn pé jíjí ni mo jí i gbé.”