Genesis 30:35 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ní ọjọ́ náà gan-an ni Labani ṣa gbogbo ewúrẹ́ ati òbúkọ tí àwọ̀ wọn ní funfun tóótòòtóó, tabi tí ó dàbí adíkálà, ati gbogbo àwọn tí wọ́n ní funfun lára, ati gbogbo àwọn aguntan dúdú, ó kó wọn lé àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ́ na li o si yà awọn obukọ oni-tototó ati alamì, ati gbogbo awọn ewurẹ ti o ṣe abilà ati alamì, ati gbogbo awọn ti o ní funfun diẹ lara, ati gbogbo oni-pupa rúsurusu ninu awọn agutan, o si fi wọn lé awọn ọmọ rẹ̀ lọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ náà gan-an ni Lábánì kó gbogbo ewúrẹ̀ tí ó lámì tàbí ilà (àti akọ àti abo, tí ó ní funfun díẹ̀ lára), pẹ̀lú gbogbo àgbò dúdú, ó sì fi wọ́n sí ìtọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.