Genesis 30:40 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jakọbu ṣa àwọn ọmọ aguntan wọnyi sọ́tọ̀, ó sì tún mú kí gbogbo agbo ẹran Labani dojú kọ àwọn ẹran tí àwọ̀ wọn ní funfun tóótòòtóó tabi tí ó dàbí adíkálà, tabi àwọn tí wọ́n jẹ́ dúdú, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣa àwọn ẹran tirẹ̀ sinu agbo kan lọ́tọ̀, kò pa wọ́n pọ̀ pẹlu ti Labani.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jakobu si yà awọn ọdọ-agutan, o si kọju awọn agbo-ẹran si oni-tototó, ati gbogbo onìpupa rúsurusu ninu agbo-ẹran Labani: o si fi awọn agbo-ẹran si ọ̀tọ fun ara rẹ̀, kò si fi wọn sinu ẹran Labani.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ó ya àwọn abo ẹran kúrò nínú agbo ẹran Lábánì, ó sì yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára àgbò, ó sì mú kí wọn máa gùn pẹ̀lú àwọn àgbò Jákọ́bù dúdú nìkan, bẹ́ẹ̀ ni ó kó agbo-ẹran jọ fún ara rẹ̀ láti ara agbo ẹran Lábánì.