Genesis 30:41 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn ẹran tí ara wọ́n le dáradára láàrin agbo bá ń gùn, Jakọbu a fi àwọn ọ̀pá náà siwaju wọn, kí wọ́n lè máa gùn láàrin wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati ẹran ti o lera jù ba yún, Jakobu a si fi ọpá na lelẹ niwaju awọn ẹran na li oju àgbará, ki nwọn o le ma yún lãrin ọpá wọnni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà kígbà tí àwọn ẹran tí ó lera bá ń gùn, Jákọ́bù yóò fi àwọn ọ̀pá wọ̀nyí lélẹ̀ níwájú wọn, ní ibi tí wọn ti ń mumi.