Genesis 31:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ní àkókò tí àwọn ẹran náà ń gùn, mo rí i lójú àlá pé àwọn òbúkọ tí wọn ń gun àwọn ẹran jẹ́ àwọn tí àwọ̀ wọn dàbí ti adíkálà ati àwọn onífunfun tóótòòtóó ati àwọn abilà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe li akokò ti awọn ẹran yún, mo si gbé oju mi soke, mo si ri li oju-alá, si kiyesi i, awọn obukọ ti o ngùn awọn ẹran jẹ́ oni-tototó, abilà, ati alamì.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ní àsìkò tí àwọn ẹran ń gùn, mo la àlá mo sì ri pé àwọn òbúkọ tí wọ́n ń gun àwọn ẹran jẹ́ oní-tótòtó, onílà àti alámì.