Genesis 31:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Angẹli Ọlọrun bá sọ pé, ‘Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wò ó pé gbogbo àwọn òbúkọ tí ó ń gun àwọn ẹran inú agbo jẹ́ aláwọ̀ adíkálà ati onífunfun tóótòòtóó ati abilà, nítorí mo ti rí gbogbo ohun tí Labani ń ṣe sí ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Gbé oju rẹ soke nisisiyi, ki o si wò, gbogbo awọn obukọ ti ngùn awọn ẹran li o ṣe tototó, abilà, ati alamì: nitori ti emi ti ri ohun gbogbo ti Labani nṣe si ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí pé, ‘Gbé ojú rẹ sókè kí o sì wò ó, gbogbo àwọn òbúkọ tí ó ń gun àwọn ẹran jẹ́ oni tótòtó, onílà àti alámì, nítorí mo ti rí gbogbo ohun ti Lábánì ń ṣe sí ọ.