Genesis 31:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Labani bá wá inú àgọ́ Jakọbu, ati ti Lea ati ti àwọn iranṣẹbinrin mejeeji, ṣugbọn kò rí àwọn ère oriṣa rẹ̀. Bí ó ti jáde ninu àgọ́ Lea ni ó lọ sí ti Rakẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Labani si wọ̀ inu agọ́ Jakobu lọ, ati inu agọ́ Lea, ati inu agọ́ awọn iranṣẹbinrin mejeji; ṣugbọn kò ri wọn. Nigbana li o jade kuro ninu agọ́ Lea, o si wọ̀ inu agọ́ Rakeli lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lábánì sì lọ sínú àgọ́ Jákọ́bù àti ti Líà àti ti àwọn ìránṣẹ́-bìnrin méjèèjì, kò sì rí ohunkóhun. Lẹ́yìn ìgbà tí ó jáde nínú àgọ́ Líà ni ó lọ sí àgọ́ Rákélì.