Genesis 31:34 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Rakẹli ni ó kó àwọn ère oriṣa náà, ó dì wọ́n sinu àpò gàárì ràkúnmí, ó sì jókòó lé e mọ́lẹ̀. Labani tú gbogbo inú àgọ́ rẹ̀, ṣugbọn kò rí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Rakeli si gbé awọn ere na, o si fi wọn sinu gãri ibakasiẹ, o si joko le wọn. Labani si wá gbogbo agọ́ ṣugbọn kò ri wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Rákélì sì gbé àwọn òrìṣà náà sínú gàárì ràkunmí, ó sì jókòó lé e lórí. Lábánì sì wá gbogbo inú àgọ́, kò sì rí ohunkóhun.