Genesis 31:42 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí kò bá jẹ́ pé Ọlọrun baba mi wà pẹlu mi, àní, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun tí Isaaki ń sìn tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù, láìsí àní àní, ìwọ ìbá ti lé mi lọ lọ́wọ́ òfo kó tó di àkókò yìí. Ọlọrun rí ìyà mi ati iṣẹ́ ọwọ́ mi ni ó fi kìlọ̀ fún ọ ní alẹ́ àná.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bikoṣe bi Ọlọrun baba mi, Ọlọrun Abrahamu, ati ẹ̀ru Isaaki ti wà pẹlu mi, nitõtọ ofo ni iwọ iba rán mi jade lọ. Ọlọrun ri ipọnju mi, ati lãla ọwọ́ mi, o si ba ọ wi li oru aná.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó bá ṣe pé Ọlọ́run àwọn baba mi, Ọlọ́run Ábúráhámù àti ẹ̀rù Ísáákì kò wà pẹ̀lú mi ni, ìwọ ì bá ti lé mi jáde lọ́wọ́ òfo. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ti rí gbogbo ìpọ́njú mi àti iṣẹ́ àṣekára tí mo fi ọwọ mi ṣe, ó sì kìlọ̀ fún ọ lóru àná.”