Genesis 31:46 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó sì sọ fún àwọn ìbátan rẹ̀ kí wọ́n kó òkúta jọ. Wọ́n sì kó òkúta jọ, wọ́n fi ṣe òkítì ńlá kan, gbogbo wọn bá jọ jẹun níbi òkítì náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jakobu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Ẹ ma kó okuta jọ; nwọn si kó okuta jọ, nwọn si ṣe òkiti: nwọn si jẹun nibẹ̀ lori òkiti na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún àwọn ìbátan rẹ̀ pé, “Ẹ kó àwọn òkúta díẹ̀ jọ.” Wọ́n sì kó òkúta náà jọ bí òkítì wọ́n sì jẹun níbẹ̀.