Genesis 31:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ó bá wí pé àwọn ẹran tí ó ní funfun tóótòòtóó ni yóo jẹ́ owó ọ̀yà mi, gbogbo ẹran inú agbo a sì bí onífunfun tóótòòtóó. Bí ó bá sì wí pé, àwọn ẹran tí ó bá ní àwọ̀ tí ó dàbí adíkálà ni yóo jẹ́ tèmi, gbogbo ẹran inú agbo a sì bí ọmọ tí àwọ̀ wọn dàbí adíkálà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o ba si wi bayi pe, Awọn abilà ni yio ṣe ọ̀ya rẹ; gbogbo awọn ẹran a si bí abilà: bi o ba si wi bayi, Awọn oni-tototó ni yio ṣe ọ̀ya rẹ; gbogbo awọn ẹran a si bí oni-tototó.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Tí ó bá wí pé, ‘Àwọn ẹran onílà ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ rẹ’, nígbà náà ni gbogbo àwọn ẹran ń bí onílà; bí ó bá sì wí pé, ‘Àwọn ẹran oni-tótòtó ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ rẹ’ nígbà náà ni gbogbo ẹran ń bi oní-tótòtó.